FOREIGN

AKB – YORUBA : Èyí ni bí àwọn obìnrin kan ṣe n fi abẹ̀ dídá sọ ara wọn di ‘fágìn’ lẹ́ẹ̀kejì
Read Time:2 Minute, 34 Second

AKB – YORUBA : Èyí ni bí àwọn obìnrin kan ṣe n fi abẹ̀ dídá sọ ara wọn di ‘fágìn’ lẹ́ẹ̀kejì

0 0

Ìròyìn tó ṣe kókó

Obinrin to n bọ pata

Wo bí àwọn obìnrin kan ṣe n sọ ara wọn di ‘fágìn’ lẹ́ẹ̀kejì

Awon obinrin kan ni orilẹede Sudan n lọ fun iṣẹ abẹ lati da abẹ fun’ra wọn ti igbeyawo wọn ba ti ku oṣu kan tabi meji ki wọn o le ro wi pe wundia ti ko ti i ni ibalopọ ri ni wọn.

Eyi n waye botilẹjẹ wi pe ọpọ ninu wọn ti dabẹ fun nigba ti wọn wa l’ọmọde – nigba ti wọn wa ni ọmọ ọdun mẹẹrin si mẹwa ni wọn maa n ṣe e.

Ni orilẹede naa to jẹ musulumi, wọn maa n ṣe eyi nipa gige idọati labia kuro. Ti wọn si ṣa ba maa n ran an pada lati le mu ki iho oju ara o kere si. Igbesẹ yii ni wọn n pe ni infibulation.

Awọn owu ti wọn fi ran yoo tu u ti obinrin ba ti ni ibalopọ. Awọn agbẹbi lo si maa n ṣe e.

Ọkan lara awọn obinrin to ṣe e, Maha sọ fun BBC pe inira pupọ ni igbesẹ naa fa fun oun.

 

Media captionÈyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀

Maha ti a fi orukọ bo ni aṣiri ti le ni ogun ọdun, o si jẹ akẹkọọjade ni fasiti kan, wa lati Ariwa orilẹede Sudan. Ofin ko si faaye gba abẹ dida fun smọbinrin nibi to ti wa.

“O dun mi pupọ, debi pe mo ni lati lọ duro si ọdọ ọrẹ mi kan fun ọpọlọpọ ọjọ titi ti ara mi fi ya nitori pe mi o fẹ ki iya mi o mọ pe mo ṣe e.

“O nira fun mi lati tọ. Bakan naa ni mi o le rin daada fun ọjọ diẹ.”

Maha lọ fun iṣẹ abẹ naa nigbati o ku oṣu meji ti yoo ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin to ju u lọ diẹ.

Obinrin to la idi silẹImage copyrightMARÍA CONEJO/BBC

Maha sọ pe “Ko ni i fi inu tan mi to ba fi mọ pe mo ti ni ibalopọ ka to o ṣe igbeyawo wa.”

“Niṣe ni yoo fi ofin de mi pe mi o gbọdọ maa jade tabi lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ.”

Ọpọlọpọ aṣa lo n polongo pe ibale obinrin ṣe pataki ṣaaju igbeyawo, eyi si lo maa n mu ki awọn obinrin kan o tun awọ fẹlẹfẹlẹ to bo ẹnu iho oju ara wọn ṣe.

Media captionÀwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Ṣugbọn, kọọrọ ni wọn ti maa n ṣe iṣẹ abẹ ‘oju ara tuntun yii’, nitori pe ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun oyinbo ni Sudan tako o.

Ọkan lara awọn agbẹbi to maa n ṣe e sọ pe lootọ ni oun korira rẹ, ṣugbọn oun maa n ṣe ti oun ba nilo owo fun itọju awọn ọmọ ọmọ oun ti iya wọn ti ku.

Botilẹjẹ wi pe ọlaju ti de, awọn obinrin kan si n ṣe e, nitori pe awọn ọkunrin kan maa n fẹ ki iyawo ti wọn yoo fẹ ẹ jẹ omidan ti ko ni ibalopọ ri.

Similar Posts:

About Post Author

Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply

Your email address will not be published.

%d bloggers like this: